IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 26 February 2026

INEC sun ọjọ idibo gomina ipinlẹ Ọṣun siwaju


Ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ti sun ọjọ idibo gomina ipinlẹ Ọṣun siwaju.


Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ, ọdun yii ni wọn kọkọ kede fun idibo naa tẹlẹ, ṣugbọn wọn ti sun un di ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹjọ bayii.


Eleyii waye nipasẹ atunṣe to de ba ofin eto idibo ilẹ wa ti ọdun 2022, ti wọn si ko awọn atunṣe naa sinuu ofin eto idibo ọdun 2026.


Ninu rẹ naa ni wọn ti sọ pe idibo aarẹ yoo waye loṣu kinni ọdun 2027 dipo oṣu keji ọdun naa ti wọn kọkọ kede tẹlẹ.

No comments:

Post a Comment