IROYIN YAJOYAJO

Friday, 27 February 2026

Osun 2026: Ojuṣe gbogbo wa ni aṣeyọri Bọla Oyebamiji - APC sọ fawọn ọmọ ẹgbẹ


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lẹkun Iwọ-oorun Ọṣun ti ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lati mọ pe agbajọwọ ni aṣeyọri idibo gomina ti yoo waye lọjọ Kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.


Ninu atẹjade kan ti alaga wọn, Hon. Ọmọlaoye Akinọla, fọwọ si lẹyin ipade apapọ ti wọn ṣe nijọba ibilẹ Ọla-Oluwa lọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ni wọn ti dupẹ lọwọ Aarẹ Tinubu, Oloye Bisi Akande, Alhaji Gboyega Oyetọla ati Ẹnjinia Akinwumi fun aduroti wọn fun ẹgbẹ naa.



Ẹgbẹ APC dupẹ lọwọ gbogbo awọn to fi erongba han lati agbegbe naa lati dupo gomina, fun bi wọn ṣe n fọwọsowọpọ pẹlu Oyebamiji lati ọjọ Kẹẹdogun oṣu Kejila ọdun to kọja ti wọn ti ṣe idibo abẹle.


Wọn ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lati ri i daju pe oludije wọn, Alhaji Bọla Oyebamiji jawe olubori ninu idibo to n bọ naa.



No comments:

Post a Comment