Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe ko si ootọ kankan ninu ariwo ipaṣipayọ owo oṣu to to biliọnu lọna mẹtala naira ti ileeṣẹ ayẹwe-owo wo, Sally Tibbot Limited, n pa kaakiri.
Wọn ni ko sẹni ti ko mọ pe ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lo wa nidi iroyin ofeege naa.
Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna fun eto iroyin, Oluọmọ Kọlapọ Alimi, fi sita ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ida meji lara ida mẹta awọn ti ileeṣẹ naa pe ni ayederu oṣiṣẹ ni wọn jẹ ojulowo oṣiṣẹ ijọba labẹ ipinlẹ Ọṣun.
Alimi ṣalaye pe digbi ni Gomina Ademọla Adeleke wa lati gba ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra lalejo lati ṣayẹwo eto iṣuna iṣejọba rẹ gẹgẹ bo ṣe ṣe pẹluu gbigbe iṣẹ fun Sally Tibbot lakọkọ.
O ni ti wọn ba sọ pe ipaṣipayọ owo wa, iṣẹjọba Oyetọla ni nitori GominaAdeleke gba awọn oluyẹwe-owo wo lati le ṣewadii ahesọ to n lọ kaakiri nigba naa pe iṣẹjọba Gomina Oyetọla fi kun iye awọn oṣiṣẹ to yẹ ki wọn maa gba owo-oṣu labẹ ijọba Ọṣun.
Alimi sọ siwaju pe inu gomina yoo dun ti wọn ba le ṣawari awọn ayederu oṣiṣẹ ti wọn jẹ ẹgbẹrun lọna mẹẹdogun yii, bẹẹ ni inu gomina yoo dun ti ajọ EFCC ati ICPC ba le ṣawari wọn nitori gomina ko lẹbọ lẹru, awọn oṣiṣẹ ijọba laarin ọdun 2018 si 2023 ni ileeṣẹ Sally Tibbot si ṣayẹwo si akọsilẹ wọn.
Ni ti Dokita Deji Adeleke, Oluọmọ Alimi ṣalaye pe nigba ti ẹgbọn gomina gbọ pe ileeṣẹ naa kede awọn ojulowo oṣiṣẹ gẹgẹ bii ayederu lo pinnu lati da si i, ki alaiṣẹ ma baa ku sipo ẹlẹṣẹ. O ni o da si i nigba ti gbogbo wọn ṣakiyesi kudiẹkudiẹ ninu abajade iwadii ileeṣẹ Sally Tibbot.
O waa fẹsun kan aṣoju ileeṣẹ naa, Sa’adat Bakrin-Ottun, pe o fi ara rẹ silẹ fun ẹgbẹ APC lati lo, amọ ṣa, gbogbo ete wọn lo ni o ti ja si pabo bayii.

No comments:
Post a Comment