Lati le mu nnkan rọrun fun awọn Kristiẹni atawọn Musulumi ti wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọṣun, Gomina Ademọla Adeleke ti din asiko iṣẹ wọn ku bayii.
Ninu atẹjade kan to jade lati ọfiisi olori awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun, Alagba Ayanlẹyẹ Aina lọjọ Kọkandinlogun oṣu Keji ọdun yii ni wọn ti sọ pe lọgan ni aṣẹ naa yoo bẹrẹ sii fidi mulẹ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, titi ti aawẹ Ramadan ati Lẹnti yoo fi pari, aago meji ọsan lawọn oṣiṣẹ yoo maa lọ sile laarin ọjọ Mọnde si Tọsidee, ti iṣẹ yoo si maa pari laago kan ọsan lọjọọjọ Jimoh.
Amọ ṣa, atẹjade naa sọ pe anfaani ayipada asiko iṣẹ yii ko kan awọn ti iṣẹ wọn jẹ koṣeemani bii awọn eleto ilera rara.
Gomina Adeleke rọ awọn oṣiṣẹ ijọba lati lo anfaani akoko aawẹ ọdun yii lati gbadura pe ki alaafia tubọ wa l'Ọṣun, ko ma si si wahala kankan paapaa bo ṣe jẹ pe ọdun yii nidibo gomina.

No comments:
Post a Comment