IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 5 February 2026

Oṣere tiata ilẹ wa nni, Aunti Ajara, ti jade laye


Ọkan lara awọn oṣerebinrin ninu tiata Yoruba, Ajara Lasisi, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Aunty Ajara la gbọ pe o ti jade laye bayii.


Lọsẹ to kọba lawọn akẹẹgbẹ rẹ jade sita pe kawọn ọmọ Naijiria ran an lọwọ.


Wọn ni o wa nileewosan to ti n gbatọju ati pe ẹrọ ti wọn fi n mi, iyẹn oxygen, lo n lo.


Ohun ti a gbọ ni pe ọmọbinrin ti ko ga pupọ yii loyun, bẹẹ ni aisan ẹdọ tun n ṣe e, eleyii to sọ ọ di ero ileewosan lati ọpọ ọjọ ṣeyin, ko to di pe o dagbere faye bayii.

No comments:

Post a Comment