IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 24 March 2026

Akọwe Apapọ Ẹgbẹ APC: Ajibọla Baṣiru kajuẹ, oun la fẹ fun saa keji - Igbimọ Agba Ọṣun


Igbimọ Agba Ọṣun ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ti sọ pe gbọn-in-gbọn-in lawọn wa lẹyin Sẹnetọ Ajibọla Baṣiru, ẹni to jẹ akọwe apapọ ẹgbẹ naa lorileede yii lọwọlọwọ.


Ninu atẹjade kan ti alaga wọn, Oloye Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, fi sita ni wọn ti sọ pe oniruuru iṣẹ takuntakun ti Ajibọla ti ṣe lori ipo naa lo fa a ti awọn fi n pe fun atunyansipo rẹ.


Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, 'Ki i ṣe ọrọ ẹnu lasan pe ọmọ wa to jẹ akọwe apapọ ẹgbẹ APC lọwọlọwọ ti lo ọpọlọpọ iriri rẹ ninu oṣelu lati yanju oniruuru ipenija to ti doju kọ ẹgbẹ wa latigba to ti wa nipo.


'Nipasẹ eyi ni ẹgbẹ wa fi n lagbara sii, to si di aayo fun gbogbo awọn ọmọ orileede yii, aṣeyọri to jẹ akọkọ iru rẹ ninu itan ẹgbẹ to ba wa nijọba lorileede Naijiria.


'Yatọ si pe ipinnu wa lati ṣatilẹyin fun saa keji Ajibọla jẹ erongba gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ APC l'Ọṣun, o tun jẹ ohun ti awa Igbimọ Agba fẹ.'


Ẹnjinia Akinwumi wa ke si gbogbo awọn aṣoju ti yoo dibo naa lati dibo wọn fun atunyansipo Dokita Ajibọla Baṣiru gẹgẹ bii akọwe apapọ ẹgbẹ APC, o si gbadura aanu irinajo fun gbogbo wọn.

No comments:

Post a Comment