Igbimọ Agba Ọṣun ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, ti ki akọwe apapọ ẹgbẹ naa, Sẹnetọ Ajibọla Baṣiru, ku oriire atunyansipo rẹ, wọn si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii aṣoju to ṣe e mu yangan.
Ninu atẹjade kan ti alaga wọn, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, fọwọ si ni wọn ti sọ pe ọgbọn oṣelu ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, Oloye Bisi Akande ati Alhaji Isiaka Gboyega ṣafihan rẹ lo fa aṣeyọri ipade apapọ to waye lọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii ọhun.
Wọn ni atunyasipo Ajibọla yoo tubọ fun un lanfaani lati ṣa gbogbo ipa rẹ fun itẹsiwaju ẹgbẹ APC pẹlu ifọwọsowọpọ awọn oloye ẹgbẹ to ku.
Igbimọ yii wa rọ gbogbo awọn oloye ẹgbẹ tuntun lapapọ ati lẹkajẹka lati mọ pe iṣọkan ati nini afojusun kannaa ṣe pataki fun aṣeyọri ẹgbẹ naa, bẹrẹ latibi idibo gomina ipinlẹ Ọṣun ti yoo waye lọjọ Kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026.

No comments:
Post a Comment