Minisita fun ọrọ ina mọnamọma lorileede Naijiria, Adebayọ Adelabu, ti kọwe fipo silẹ.
Adelabu, ẹni to je igbakeji gomina fun banki apapọ ilẹ wa nigba kan ri, fi lẹta rẹ ṣọwọ si Aarẹ Tinubu nipasẹ akọwe funjọba apapọ lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹta ọdun yii
O dupẹ lọwọ aarẹ fun anfaani to fun un lati sin orileede Naijiria, o si sọ pe oun fipo silẹ lati le raaye gbaju mọ erongba oun lati di gomina ipinlẹ Ọyọ.


No comments:
Post a Comment