Olojudo ti Ido Ọṣun, Ọba Ọlayinka Iṣọla Jokotọla, ti paṣẹ pe ki wọn ti olu ijọ God of White Calling for All Souls Ministries to wa ninu ilu naa pa lori ẹsun pe wọn fẹẹ da wahala ẹsin silẹ.
Oludasilẹ ijọ naa, Woli Ọdẹyẹmi Ezekiel lo ko awọn ọmọ ijọ rẹ lọ si odo Ọṣun niluu Oṣogbo laipẹ yii nibi ti wọn ti sọ pe awọn n le awọn ẹmi aimọ jade nibẹ.
Lẹyin ti wọn ṣe tiwọn lawọn oniṣẹṣe kan ko ara wọn jọ, ti wọn si lọ pa aja sinu ṣọọsi naa pẹlu ikilọ pe oju awọn ọmọ ijọ yẹn yoo ri ju bẹẹ lọ ti wọn ba tun ṣan aṣọ iru igbesẹ bẹẹ ṣoro.
Ninu atẹjade kan ti Eesa Ido-Ọṣun, Oloye Basiru Oyewale, fi sita lonii ọjọ Tusidee lo ti di mimọ pe gbogbo igbiyanju lati ri i pe pasitọ naa sọ tẹnu rẹ ni ko so eso rere nitori ko yọju si aafin lẹyin ti wọn ranṣẹ pe e.
Atẹjade ọhun ni iwa ti pasitọ naa hu jẹ eyi to le da ija ẹsin nla silẹ, iru eyi ti ko si ṣẹlẹ niluu Ido-Ọsun ri, o si pọn dandan ki ilu dena iru nnkan bẹẹ.

No comments:
Post a Comment