IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 11 April 2026

A ko nii faaye gba awọn arugbo lati dupo ninu ẹgbẹ oṣelu ADC - Nafiu Bala


Alaga igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, Nafiu Bala, ti sọ pe ko si aaye fun ẹnikẹni to ba ti ju ọmọ ọdun marunlelaadọta lọ lati dupo ninu ẹgbẹ naa.


Nafiu Bala ṣalaye pe pupọ iṣoro ati idaamu ti orileede yii n koju ko ṣẹyin bi awọn arugbo ti wọn ko ni agbara iṣakoso mọ ṣe taku sinu ipo oṣelu.


Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe laipẹ yii ni Bala ti sọ siwaju pe asiko awọn ọdọlangba la wa yii, awọn ọdọ nikan ni wọn mọ oniruuru igbesẹ ti wọn le gbe lati ran orileede Naijiria lọwọ.


O ni awọn arugbo oloṣelu ti ja awọn ọmọ orileede yii kulẹ, nitori naa, wọn gbọdọ faaye gba awọn ọdọ lati bọ sipo iṣejọba bayii.


Nafiu Bala sọ pe ilẹkun ẹgbẹ oṣelu ADC ṣi silẹ fun awọn ọdọ ti wọn ba fẹẹ dupo, bẹẹ ni gbogbo igbesẹ lawọn n gbe lati jẹ ki ẹgbẹ naa fẹsẹ rinlẹ sii lorileede Naijiria.

No comments:

Post a Comment