IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 12 April 2026

Ẹni ti ki i bẹru lati sọ otitọ, to si ni ọpọlọ oṣelu ni Ẹnjinia Akinwumi - Igbimọ Agba Ọṣun


Igbimọ Agba ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọṣun ti ba alaga wọn, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, dawọọdunnnu ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kọkandinlaadọrun to pe lori oke-eepẹ.


Ninu atẹjade kan ti akọwe igbimọ naa, Hon. Ọmọlaoye Akintọla fi sita ni wọn ti sọ pe ko si iye ọrọ ti awọn fẹẹ sọ to kajuu iru eeyan ti Akinwumi jẹ gan an.


Wọn ni oloootọ eeyan, ti ki i woju lati la ọrọ mọlẹ ni baba yii, o si ti fi han pe ọlọpọlọ pipe ninu oṣelu ni oun latigba to ti jẹ alaga igbimọ naa latibẹrẹ pẹpẹ.


Igbimọ Agba Ọṣun sọ siwaju pe ẹni ti oye iṣejọba tiwantiwa ye pupọ ni Akinwumi, ipa rẹ ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun ko si lẹgbẹ rara.


Wọn wa gbadura pe ki Allah tubọ fun baba naa ni ẹmi gigun ninu ọgbọn ati ifọkanbalẹ pẹlu alaafia.

No comments:

Post a Comment