Lati le wa ojutuu si idakureku ina ijọba to jẹ ipenija nla fawọn eeyan ipinlẹ Ọṣun bayii, Gomina Ademọla Adeleke ti ranṣẹ si awọn adari ileeṣẹ apinna lẹkun Ibadan, Ibadan Electricity Distribution Company (IBEDC), lati wa sọ tẹnu wọn lori ẹ.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina, Mallam Ọlawale Rasheed, fi sita ni Adeleke ti sọ pe inu oun ko dun si ipa buburu ti aisi ina ijọba yii ni lori awọn olokoowo kekeke atawọn araalu, o ni IBEDC ni lati ṣalaye nipa ipenija naa lati le wa ọna abayọ si i.
O ni "Mo ti gbọ ọpọlọpọ ọrọ kaakiri awọn ilu nlanla. Ọpọ okoowo lo n dẹnukọlẹ. A ko le tẹ siwaju bi eleyii. Mo fẹẹ ranṣẹ si awọn adari IBEDC fun ifikunlukun.
"A mọ pe ọrọ to ni owo to pọ ninu ni ọrọ ina ijọba. Bo tilẹ jẹ pe ọrọ ijọba apapọ ni, iya n jẹ wa l'Ọṣun pupọ. A gbọdọ ṣiṣẹ papọ pẹlu ajọ IBEDC fun igbesẹ ti a le gbe kiakia.
"Gẹgẹ bii ijọba, igbesẹ ọjọ iwaju jẹ lati jẹ ki orisun ina pọ sii, ijọba wa si n gbe igbesẹ lori eleyii. Ipinlẹ wa ti ni ofin to nii ṣe pẹlu ina mọnamọna, a maa gbe ajọ ti yoo maa ṣakoso bi awọn to fẹẹ da ileeṣẹ ina mọnamọna silẹ ni laisẹnsi.
"Nigba ti iyẹn n lọ lọwọ, a gbọdọ ba awọn IBEDC sọrọ lori igbesẹ kiakia ti a le gbe. A maa ṣepade pẹlu gbogbo awọn ti ọrọ kan lati wa ojutu si wahala yii."

No comments:
Post a Comment