IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 12 April 2026

A ti ba awọn araalu sọrọ, o si han gbangba pe wọn n fẹ ipinlẹ Ọṣun tuntun - Oyebamiji


Oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Alhaji Munirudeen Bọla Oyebamiji, ti sọ pẹlu idaniloju pe oun yoi jawe olubori ninu ibo ọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun yii.


O ni oun ati gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣiṣẹ pupọ kaakiri lati ba awọn araalu sọrọ, o si daju pe didun lọsan yoo so.


Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ nibi adura ti wọn ṣe fun ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kọkandinlaadọrun ti alaga Igbimọ Agba Ọṣun, Ẹnjinia Sọla Akinwumi, ni Oyebamiji ti sọrọ naa niluu Ilobu nipinlẹ Ọṣun.


Oyebamiji sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ kan to n lọ kaakiri pe agbara ijọba apapọ lawọn fẹẹ lo lati fi rọwọ mu ninu idibo to n bọ ọhun.


O ni awọn araalu ni wọn ṣetan lati fi ibo wọn le Gomina Ademọla Adeleke danu, nitori wọn n pongbẹ fun ipinlẹ Ọṣun tuntun.


Oyebamiji sọ siwaju pe gbogbo kọrọkọndu ipinlẹ Ọṣun lawọn ti de lati ba awọn araalu sọrọ, wọn si ti sọ pe awọn n reti iṣejọba ẹgbẹ APC loṣu kẹjọ ọdun yii.


O wa ṣapejuwe Ẹnjinia Akinwumi gẹgẹ bii oloṣelu to yanrannti, ati adari to ti lapa rere ninu ẹgbẹ APC, o si gbadura pe ki Ọlọrun fun un lẹmi gigun ati alaafia.


Ninu ọrọ rẹ, Ẹnjinia Akinwumi dupẹ lọwọ Oyebamiji, o si ke si awọn araalu lati dibo wọn fun ẹgbẹ APC loṣu Kẹjọ.


Bakan naa ni akọwe Igbimọ Agba Ọṣun, Hon. Ọmọlaoye gba awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun niyanju pe ẹgbẹ APC nikan lo ni imọlara ohun ti wọn n la kọja, to si le wa ojutu si i, nitori naa, ki wọn dibo wọn fun Oyebamiji gẹgẹ bii gomina.

No comments:

Post a Comment