IROYIN YAJOYAJO

Monday, 13 April 2026

Ọmọ ilu Iragbiji ti ko ba ṣe ti Bọla Tinubu, ọmọ ale ni - Aragbiji


Aragbiji ti ilu Iragbiji nipinlẹ Ọṣun, Ọba Abdur-Rasheed Ọlabomi ti sọ pe ọmọ ilu naa; yala nile tabi loke-okun, ti ko ba ṣe ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ọmọ ale ni.


Nibi eto kan ni Ọba Ọlabomi ti sọrọ naa laipẹ yii gẹgẹ bo ṣe wa ninu fọnran fidio kan to n lọ kaakiri ayelujara bayii.


O ni ko tọ si ọmọ ilu Iragbiji kankan lẹnu, paapaa awọn ọlọmọọba, lati fẹnu ṣaata Bọla Tinubu, koda bi wọn jẹ oloṣelu tabi bẹẹ kọ.

No comments:

Post a Comment