IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 30 April 2026

ADC: Najeem Salaam gboṣuba fun idajọ ile-ẹjọ to ga julọ, o yọ ṣuuti ete si ajọ INEC


Oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ asia ẹgbẹ African Democratic Congress, ADC, Rt. Hon. Najeem Fọlaṣayọ Salaam, ti kan saara si idajọ ti ile-ẹjọ to ga julọ lorileede yii gbe kalẹ lori ẹjọ ti igun kan ninu ẹgbẹ ADC pe awọn adari rẹ.


O ni bi ile-ẹjọ naa ṣe fagile idajọ to ti wa nilẹ tẹlẹ ninu eyi ti wọn ti ni igbimọ ti Sẹnetọ David Mark jẹ adari fun ko laṣẹ lati dari ẹgbẹ naa jẹ ohun to bọ si asiko pupọ, to si wa lati daabo bo ilana ofin.


Ninu atẹjade kan ti alakoso agba fun ikọ ipolongo ibo oludije fun ẹgbẹ ADC, Hon. Ṣẹgun Ọlanibi fi sita ni Dokita Salaam ti gboṣuba fun Onidajọ Mohammed Lawal Garba fun bo ṣe taari idajọ ile-ẹjọ giga ti ko nitumọ ọhun danu.


O ni idajọ naa ti fi han pe ile-ẹjọ jẹ opo to lagbara ninu ijọba tiwantiwa, o si jẹ ireti ikẹyin fun awọn araalu. O ni idajọ naa ti dena igbesẹ awọn alagbara kan lati ko awọn ẹgbẹ alatako ni papamọra lorileede yii.


Salaam bu ẹnu atẹ lu ajọ eleto idibo, INEC, o ni ṣe ni ajọ naa ati ẹgbẹ to n ṣejọba lọwọ n ṣe ayọjuran si ọrọ ẹgbẹ ADC. O ni ajọ INEC ko ni awijare kankan pẹlu bi wọn ṣe yọ orukọ awọn adari ẹgbẹ naa kuro ninu pọta wọn.


Salaam wa ke si awọn ọmọ ẹgbẹ nipinlẹ Ọṣun lati fọkanbalẹ, o ni digbi ni ẹgbẹ ADC wa, oun si nigbagbọ pe ẹgbẹ naa yoo rọwọ mu ninu idibo gomina oṣu kẹjọ ọdun yii pẹlu bi awọn eeyan ẹsẹkuuku ṣe n rọ kẹtikẹti wọle bayii.


O ni kikoni-ni-papa-mọra pẹlu fifi oniruuru nnkan tan awọn araalu ni ẹgbẹ APC gbojule, ṣugbọn awọn araalu ni ifẹ tootọ si ẹgbẹ ADC nitori ẹgbẹ to ni imọlara ohun ti wọn n la kọja ni.

No comments:

Post a Comment