IROYIN YAJOYAJO

Friday, 1 May 2026

AMBO ranṣẹ itunu si awọn oṣiṣẹ ijọba, o ṣeleri iṣejọba ti yoo fi aye rọ wọn lọrun l'Ọṣun


Oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Alhaji Bọla Oyebamiji, ti gboṣuba fun awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun fun ipa ribiribi ti wọn n ko lori idagbasoke ati itẹsiwaju agbegbe wọn.


Ninu atẹjade kan ti ọfiisi to n ri si ipolongo ibo fun AMBO, iyẹn, Project AMBO-ICG Media Office, fi sita lati ki awọn oṣiṣẹ ku ayẹyẹ ayajọ ọjọ wọn, ni Oyebamiji ti fi da wọn loju pe igbayegbadun wọn ni yoo jẹ ijọba oun logun ti oun ba depo gomina.


Oyebamiji kan saara si wọn fun ẹmi ifọkansin, ifaraẹnijin ati ipinnu wọn fun ilọsiwaju eto ọrọ-aje nipinlẹ Ọṣun lai fi ti oniruuru ipenija ti wọn n doju kọ ṣe. O ni gbogbo ilakaka wọn yii loun ri, ti gbogbo rẹ si lere.


Gẹgẹ bo ṣe wi, "Awọn oṣiṣẹ ijọba ni igi lẹyin ọgba orileede yii, o si tọ lati tọju awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bii ogbona gbongbo ninu iṣẹ idagbasoke."


O ni gbogbo ibi ti oun ti ṣiṣẹ ti jẹ ki oun ni iriri ati imọlara ohun to nii ṣe pẹlu awọn oṣiṣẹ. O ni iṣejọba oun ko nii fi ọrọ ipenija awọn oṣiṣẹ ijọba ṣere rara, kiakia lawọn yoo maa wa ojutuu si i.


O ni oun ko nii fi sisan owo oṣu ati ajẹmọnu wọn falẹ rara, gbogbo igbesẹ ti yoo mu ki aye rọ awọn oṣiṣẹ ijọba lọrun nibamu pẹlu eto ọrọ-aje orileede yii lawọn yoo maa ṣe.


Oyebamiji tun ranṣẹ itunu si awọn oṣiṣẹfẹyinti onimọdamọda, o ni ki wọn fọkan balẹ, asiko itura wọn ti de. O ni wọn ti sin ijọba Ọṣun daradara, wọn gbọdọ gbadun.


O ṣeleri awọn eto ti yoo mu ki ipese iṣẹ lọpọ yanturu wa fun awọn ọdọ, bẹẹ ni awọn olokoowo kekeke yoo lanfaani lati ṣiṣẹ ti yoo mu ere wa fun wọn.


Oyebamiji tun ṣeleri eto ilera to muna doko, eto ẹkọ to yanrannti ati eto aabo ni tile-toko nipinlẹ Ọṣun.

No comments:

Post a Comment