IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 30 April 2026

Ẹgbẹ APC kede oludije funpo ṣenetọ lẹkun Iwọ-Oorun Ọṣun


Awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC ni ẹkun Iwọ-Oorun Ọṣun ti kede Dokita Akinade Akanmu Ogunbiyi gẹgẹ bii oludije ti yoo gbe asia ẹgbẹ naa ninu idibo ile igbimọ aṣofin agba lati agbegbe naa ni ọdun to n bọ.


Nibi ipade ti wọn ṣe lọjọ Tọsidee, ọgbọnjọ oṣu kẹrin, ọdun yii nilee Ọjọgbọn Ladipọ niluu Iwo ni wọn ti ṣekede naa.


Ninu atẹjade kan ti Ọnarebu Ọmọlaoye Akintọla fi sita lorukọ awọn agbaagba ọhun ni wọn ti sọ pe awọn mẹwaa ni wọn jade lati du tikẹẹti naa.


Awọn mẹwẹẹwa ọhun ni Ogunbiyi, Bade Falade, Dọtun Babayẹmi, Basiru Adewinmbi, Peter Ogundeji, Mojeed Oluogun, Amere Gafar, Adegbenge Suraju Salawu, Adebayọ Waliyu Ọladosu ati Jẹnẹra Adeniran.


Ọmọlaoye ṣalaye pe lẹyin ifikunlukun to peye, awọn agbaagba ọhun fọwọ si orukọ Ogunbiyi lati ẹkun idibo Iwo gẹgẹ bii oludije funpo sẹnetọ lati Iwọ-Oorun Ọṣun ninu idibo apapọ ọdun 2027.


Wọn dupẹ lọwọ awọn alakoso ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun fun anfaani ti wọn fun wọn to mu wọn ṣaṣeyọri ọhun.

No comments:

Post a Comment