IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 14 April 2026

L'Ọṣun, awọn ẹṣọ alaabo ba oju ẹgbẹ Accord jẹ, wọn gba ọkada lọwọ ẹgbẹ APC


Wamuwamu ni gbogbo awọn adari ẹka ẹṣọ alaabo ilẹ wa ti wọn wa nipinlẹ Ọṣun pe sibi eto kan ti awọn alaga ijọba ibilẹ ti wọn jẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC ti pin ọkada ọọdunrun fun wọn lati le fi kin wọn lọwọ ninu iṣẹ aabo ilu ti wọn n ṣe.


Tẹ o ba gbagbe, lati bii ọsẹ mẹta nijọba Gomina Ademọla Adeleke ati ẹgbẹ oṣelu Accord ti n pariwo pe awọn ẹṣọ alaabo ko gbọdọ gba ọkada tabi mọto ti awọn alaga ẹgbẹ APC ba ra fun wọn.


Ohun ti wọn sọ ni pe owo to jẹ ti awọn ijọba ibilẹ l'Ọṣun tijọba apapọ gbẹsẹ le latinu oṣu keji ọdun to kọja ni wọn ti n yọnda fun awọn APC lodi si aṣẹ ile-ẹjọ.


Ṣugbọn nigba to n gba awọn ọkada naa niluu Oṣogbo lọjọ Tusidee ọsẹ yii, kọmisanna funleeṣẹ ọlọpaa l'Ọṣun, Ibrahim Gotan, sọ pe ojuṣe gbogbo eeyan ni ọrọ eto aabo, ki i ṣe ti ẹni kan ṣoṣo.


O dupẹ lọwọ awọn alaga ẹgbẹ APC fun igbesẹ nla naa, eleyii to ni yoo tubọ mu ki iṣẹ awọn rọrun sii, bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ Aarẹ Tinubu fun anfaani ominira to fun awọn ijọba ibilẹ.


Ṣaaju ni alaga ALGON nipinlẹ Ọṣun, Hon. Idowu Abiọdun sọ pe ọrọ aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun jẹ ẹgbẹ APC logun pupọ, idi si niyẹn ti wọn fi ra obitibiti ọkada naa lati le tubọ mu ki iṣẹ awọn ẹṣọ alaabo yọ.

No comments:

Post a Comment