Igbimọ Agba ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọṣun ti gboju aagan si ọrọ kan ti wọn lo jade laipẹ yii lẹnu ọkan lara awọn to n dupo Sẹnetọ lagbegbe Iwọ-Oorun Ọṣun, Dokita Akin Ogunbiyi.
Nigba ti awọn adari ẹgbẹ lagbegbe Iwọ-Oorun Ọṣun ṣepade kan niluu Iwo pẹlu awọn to fẹẹ du tikẹẹti ẹgbẹ naa lọsẹ to kọja ni wọn ni Ogunbiyi sọ pe Aarẹ Tinubu ṣepade pẹlu awọn oludije funpo gomina nigba yẹn, to si sọ fun awọn pe oun ko reti oludije kankan funpo gomina latinu ẹgbẹ APC.
Gẹgẹ bi Ogunbiyi ṣe sọ ninu fọnran fidio naa, Gomina Adeleke ni Aarẹ Tinubu fẹẹ gbaruku ti ko too di pe gomina ana l'Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla yari.
Ṣugbọn ninu atẹjade kan ti alaga Igbimọ Agba Ọṣun, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi fọwọ si, igbimọ naa sọ pe iru ọrọ bẹẹ ko yẹ lati jade latẹnu ẹni to lorukọ ninu ẹgbẹ.
Akinwumi ni ki i ṣe nnkan to ba iwa ijolootọ ninu oṣelu APC mu rara nitori ohun to ṣẹlẹ nibi ipade ti Aarẹ ba awọn oludije naa ṣe yatọ gedengbe si ọrọ ti Ogunbiyi sọ ọhun.
O ni "Looto ẹni ti a bu ọla fun pupọ ninu ẹgbẹ oṣelu wa ni Dokita Akinade Ogunbiyi, ṣugbọn inu wa ko dun si ọrọ ti wọn lo sọ yii, o si tako iwa ẹgbẹ wa.
"Mo fẹẹ kilọ fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wa, lai fi ti bi ẹnikẹni ṣe jẹ ṣe, pe ki wọn ṣọra pẹlu ọrọ ti wọn ba mọ pe awọn araalu le ṣi tumọ niwọn igba ti ẹgbẹ wa jẹ eyi to ni ofin to n dari wa.
"Nipari, mo fẹẹ rọ awọn araalu lati maṣe fọkan si gbogbo ọrọ ti wọn lo sọ ọhun."

No comments:
Post a Comment