Igbimọ ti wọn gbe kalẹ lati ṣeto ipolongo ibo fun saa keji Gomina Ademọla Adeleke ti sọ pe aṣiṣe ni orukọ ọga agba Rave FM, Dokita Fẹmi Adefila, to wa nibẹ.
Akọwe igbimọ ipolongo ọhun, Hon. Bọla Ajao, sọ ninu lẹta kan to kọ si Adefila lọjọ kejilelogun oṣu kẹrin, ọdun yii pe ọtọ lorukọ ẹni ti wọn fẹẹ kọ sibẹ.
Ajao ni Dokita Fẹmi Adegbọla ni wọn fẹẹ kọ dipo Fẹmi Adefila to wa nibẹ.
O ni awọn mọ iru iṣẹ ti Adefila n ṣe, awọn si kabamọ aṣiṣe naa.

No comments:
Post a Comment