Laarin awọn aṣofin ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ ti wọn darapọ mọ ẹgbẹ APC l'Ọṣun, Sẹnetọ Ajagunla Fadeyi Olubiyi nikan ni ko ri tikẹẹti gba lati pada si Abuja.
Nibi idibo abẹle ẹgbẹ APC Ọṣun lati yan sẹnetọ ti yoo gba tikẹẹti fun idibo apapọ ọdun to n bọ, eyi to waye lọjọ Mọnde to kọja, ni wọn ti bojuu Ajagunla, ọmọ ilu Ila, to n ṣoju awọn eeyan Aaringbungbun Ọṣun lọwọlọwọ, jẹ.
Ọmọbibi ilu Oṣogbo, Amofin Agba Kunle Rasheed Adegoke ni igbimọ to ṣakoso idibo naa kede pe o jawe olubori, ti wọn si fun ni tikẹẹti ẹgbẹ APC.
Ni Iwọ-Oorun Ọṣun, Dokita Akin Ogunbiyi lo jawe olubori, oun lo si gba tikẹẹti lati kojuu Sẹnetọ Lere Oyewumi, ọmọ ẹgbẹ Accord, ninu idibo apapọ ọdun to n bọ.
Sẹnetọ Adenigba Fadahunsi ni wọn fun ni tikẹẹti ni Ila-Oorun Ọṣun lati pada sile igbimọ aṣofin agba fun saa kẹta.
Awọn mẹrẹẹrin to ku ti wọn jọ kọwọrin pẹlu Ajagunla lọ sinu ẹgbẹ APC ni Sẹnetọ Fadahunsi, Hon. Oluwọle Ọkẹ, Hon. Sanya Omirin ati Hon. Taofeek Ajilesoro, gbogbo wọn ni wọn si ri tikẹẹti gba lati agbegbe wọn.
Oju ọtọọtọ lawọn onwoye fi wo ọrọ naa. Ọpọ lo sọ pe bi ẹgbẹ APC ṣe fojuu Ajagunla rare lai wo ti aṣaaju wọn, Oloye Bisi Akande, ti wọn jọ jẹ ọmọ ilu ṣe, ko bojumu to, bẹẹ ni ọpọ gbagbọ pe ọkunrin aṣofin yii ko gbe iṣiro le ọrọ rẹ daadaa ko to kuro ninu ẹgbẹ to fun un lanfaani lati di sẹnetọ.

No comments:
Post a Comment