IROYIN YAJOYAJO

Monday, 18 May 2026

Awọn ọmọ ẹgbẹ Accord niluu Mọdakẹkẹ ṣeleri atilẹyin fun Oyedọtun


Awọn ọmọ ẹgbẹ Accord  niluu Mọdakẹkẹ ti ṣeleri lati duro ti ọkan lara wọn, Samuel Oyedọtun, ẹni to n dije lati gba tikẹẹti ẹgbẹ naa fun ipo ile igbimọ aṣofin apapọ lorileede yii.


Wọn ṣalaye pe oniruuru akọsiilẹ iṣẹ rere ati ipa to ti ni lẹsẹkuuku ṣafihan rẹ gẹgẹ bii ẹni to kunju osunwọn funpo naa.


Aṣaaju ẹgbẹ naa niluu Mọdakẹkẹ, Ọladoṣu Oyebisi, ṣalaye pe gbọn-in-gbọn-in lawọn wa lẹyin Oyedọtun, o si rawọ ẹbẹ si Gomina Adeleke atawọn aṣaaju ẹgbẹ naa lati fun un lanfaani.


Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, fun ọpọ ọdun ni wọn ti rẹ ilu Mọdakẹkẹ jẹ ninu eto oṣelu ni Ila-Oorun Ọṣun, ni bayii ti Oyedọtun ti fi han pe ojulowo ọmọ ẹgbẹ Accord loun, to si ni gbogbo amuyẹ, o yẹ ki wọn fun un lanfaani.


O ni awọn ṣetan lati ṣiṣẹ gidigidi fun atunyansipo Gomina Adeleke ninu idibo oṣu Kẹjọ, bẹẹ ni obitibiti ibo n duro de ẹgbẹ naa niluu Mọdakẹkẹ lasiko idibo apapọ.


Bakan naa ni oludamọran pataki fun Adeleke, Ọgbẹni Banjọ Oloke, sọ pe, fun ipin-dọgbandọgba, agbegbe Ifẹ lo yẹ ki sẹnetọ ti yoo ṣoju Ila-Oorun Ọṣun ti wa.


O ni Oyedọtun kajuẹ, o konimọra, o si jẹ ọlọpọlọ pipe ti yoo ṣoju awọn eeyan Ifẹ/Ijeṣa daadaa nile igbimọ aṣofin apapọ.


Oloke rọ awọn oloṣelu lagbegbe naa lati gbe ọrọ imọtaraẹni sẹgbẹ kan, ki wọn si kọwọ ti oludije to jẹ olootọ lẹyin nitori ọrọ yii ni nnkan ṣe pẹlu ọjọ-ọla Ila-Oorun Ọṣun.

No comments:

Post a Comment