IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 26 May 2026

Ajagunla fẹsun kan ẹgbẹ APC Ọṣun, o ni inu otẹẹli ni wọn ti n kọ esi idibo


Sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan Aaringbungbun Ọṣun nile igbimọ aṣofin agba lorileeee yii, Sẹnetọ Fadeyi Olubiyi Ajagunla, ti sọ pe oun ko faramọ esi idibo abẹle to waye nipinlẹ Ọṣun lọjọ kọkandinlogun oṣu karun, ọdun yii.


Ninu atẹjade kan to fi sita lo ti sọ pe ṣe lawọn kan mọ-ọn-mọ yọwọ oun lawo ninu idibo abẹle naa ti wọn fi sọ pe ki i ṣe oun loun wọle.


O ni ko sibikankan ti wọn ti ṣeto idibo ni aaringbungbun Ọṣun lọjọ naa, inu otẹẹli lawọn kan si joko si ti wọn fi kọ esi idibo abẹle to wu wọn jade.


O ke si awọn agbaagba ẹgbẹ naa l'Ọṣun lati tete wa ojutu si ọrọ naa, o si rọ awọn alatilẹyin rẹ lati maṣe sọ ohunkohun lori ọrọ naa mọ titi ti yoo fi loju.


Ṣaaju ni igbimọ to ṣeto idibo abẹle naa ti kede Amofin-Agba Kunle Adegoke gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu idibo abẹle naa pẹlu ibo to le ni ẹgbẹrun mẹrindinlọgbọn, nigba ti wọn ni Ajagunla ṣe ipo keji pẹlu ibo to le ni ẹgbẹrun mẹtala.


Tẹ o ba gbagbe, abẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ajagunla ti wọle ninu ibo ọdun 2023, inu ọdun yii lo si fi ẹgbẹ naa silẹ to ta kọsọ sinu ẹgbẹ APC nibi to ti ba ijakulẹ pade bayii.

No comments:

Post a Comment