IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 16 May 2026

2027: Gbogbo awọn oludije lati Iwọ-Oorun Ọṣun gba lati ṣatilẹyin fun Ogunbiyi


Gbogbo awọn to gba fọọmu ẹgbẹ APC lati dije funpo sẹnetọ ni iha Iwọ-Oorun Ọṣun la gbọ pe wọn ti fohun ṣọkan lati ṣatilẹyin fun Dokita  Akin Ogunbiyi bayii.


Ninu abajade ipade ti awọn agbaagba ẹgbẹ naa ṣe pẹlu awọn oludije yii niluu Iwo la gbọ pe wọn ti fẹnuko.


Gẹgẹ bi ọkan lara awọn agbaagba ẹgbẹ naa, Hon. Ọmọlaoye Akintọla, ṣe sọ, ipade naa waye lati ri i daju pe ko si ikunsinu kankan; ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo abẹle, ki gbogbo wọn si lọ sinu idibo gomina oṣu kẹjọ pẹlu iṣọkan.


Wọn dupẹ lọwọ awọn oludije naa pẹlu awọn adari ẹgbẹ fun anfaani ọhun.


Awọn to fi erongba han lati dije ki wọn to mu Ogunbiyi ni Ọmọọba Dọtun Babayemi, Hon. Bade Falade; Dr. Peter Ogundeji; Rt. Hon Gafar Amere; Rtd General Bashir  Adewinbi; Dr. Surajudeen A. Salawu; Rtd Bridg.Gen. Adeniran; Dr. Mojeed Oluogun; ati Hon. Adebayo W.Oladosu.

No comments:

Post a Comment