Ẹgbẹ kan ti ko ni nnkan ṣe pẹlu oṣelu nilẹ Ijeṣa, Ijeṣa Unites, ti ṣeleri lati ṣatilẹyin fun erongba Hon. Sam Oyedọtun lati dije funpo ile igbimọ aṣofin agba lorileede yii lati Ila-Oorun Ọṣun.
Ninu atẹjade kan ti alakoso ati akọwe ẹgbẹ naa, Hon. Ọlanrewaju Ogedengbe ati Alhaja Mariam Adesoye, fi sita ni wọn ti sọ pe ohun to bojumu ni ki ipo sẹnatọ lọ si ẹkun idibo Ifẹ lẹyin to ti lo ọdun mẹjọ gbako ni Ijeṣa.
Wọn ni ẹgbẹ oṣelu to ba mọ nnkan to n ṣe, to si fẹ ibo awọn araalu lọdun 2027, yoo mọ pe ẹkun idibo Ifẹ lo yẹ ki wọn ti mu oludije funpo Sẹnetọ.
Ninu atẹjade yii ni wọn ti sọ pe awọn ti woye ọrọ oṣelu agbegbe Ifẹ/Ijẹsa, awọn si fẹnuko pe, lai ni si iyanjẹ, agbegbe Ifẹ lo yẹ ko fa oludije funpo sẹnetọ kalẹ.
Wọn ni, "Lọwọlọwọ bayii, Sẹnetọ Francis Fadahunsi lati ilẹ Ijeṣa ti lo ọdun mẹjọ labẹ asia ẹgbẹ PDP, oun si tun ni ẹgbẹ oṣelu APC fa kalẹ. Ẹ jẹ ki awọn ẹgbẹ oṣelu yooku lọ si agbegbe Ifẹ.
"Ṣe la maa n pin ipo yẹn laarin ara wa, Ijeṣa ti lo ọdun mẹjọ, ẹkun idibo Ifẹ lo ku. Awọn eeyan agbegbe Ariwa Ifẹ, Guusu Ifẹ, Ila-Oorun Ifẹ, Aaringbungbun Ifẹ, to fi mọ Mọdakẹkẹ gbọdọ ni iriri idagbasoke. Idi si niyii ti a fi kọwọ ti Oyedọtun lẹyin.
"A wo saakun gbogbo awọn oludije ti wọn jade, a si ri i pe Oyedọtun ta wọn yọ. Ọmọbibi ilu Mọdakẹkẹ ni, asiko si ti to fun ilu yẹn lati ri ọwọja idagbasoke oṣelu.
"Olootọ ni Oyedọtun, ki i foju paayan rẹ, o ni imọlara ilakọja awọn araalu, a si mọ pe yoo ṣe daadaa to ba depo."

No comments:
Post a Comment