IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 2 May 2026

A ko gbọdọ sọ ireti nu nipa iran Yoruba - Gomina Makinde


Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinia Ṣeyi Makinde, ti sọ pe ireti ṣi n bẹ fun iran Yoruba lai fi ti ipenija to n doju kọ iran naa lọwọlọwọ ṣe.


Lasiko ti Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, fi Oloye Olufunṣọ Amosun jẹ oye Yeye Mọremi Oodua, eleyii to waye lagbala aafin rẹ niluu Ileefẹ, ni Makinde sọrọ yii.


O ni to ba ṣe e ṣe fun Ọba Ogunwusi lati ko gbogbo awọn lookọlookọ jọ sibi ayẹyẹ naa, lai fi ti ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ti gbogbo wọn wa ṣe, o daju pe ireti n bẹ fun orileede Yoruba.


O ni iru nnkan to ṣẹlẹ nibi ayẹyẹ naa lo yẹ ki gbogbo awọn ọmọ Yoruba maa lepa, nibi ti ko ti si ẹgbẹ PDP tabi APC, ti gbogbo wọn duro ninu ifẹ.



O wa gbadura pe ki Ọlọrun lọra ẹmi oloye tuntun ọhun fun itẹsiwaju ipa ribiribi to n ko fun ọmọniyan.


Lara awọn to wa nibi eto naa ni Sẹnetọ Ibikunle Amosun, Ọtunba Gbenga Daniel, Amofin Agba Babatunde Raji Faṣọla, Dokita Kayọde Fayẹmi, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla, Iyaafin Bọla Ọbasanjọ, Musiliu Ọbanikoro, Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, pẹlu ọpọlọpọ awọn iyawo gomina tẹlẹ ri kaakiri ilẹ Yoruba 


Bakan naa ni awọn ori-ade kaakiri ilẹ Yoruba ko gbẹyin nibi ayẹyẹ to tun ṣe kongẹ ayajọ ọjọọbi ọgọta ọdun ti Oloye Funṣọ Amosun de ile aye.

No comments:

Post a Comment