IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 2 May 2026

O ma ṣe o! Iyawo alaga ẹgbẹ oṣelu APC l'Ọṣun, Fatimoh Lawal, jade laye


Kaakiri ipinlẹ Ọṣun ni wọn ti n ranṣẹ ibanikẹdun si alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Sooko Tajudeen Lawal, lori iku iyawo rẹ, Alhaja Fatimoh OreOluwa Lawal.


Alhaja Lawal la gbọ pe o ku sileewosan OAUTHC niluu Ileefẹ lọjọ Ẹti, Fraidee to kọja lẹyin aisan ranpẹ.


Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ, Ẹnjinia Aṣalu Ayọdele David (Asler), ṣapejuwe obinrin naa gẹgẹ bii ẹni to konimọra, to si duro ti ọkọ rẹ.


O gbadura pe ki Ọlọrun tu gbogbo ẹbi Lawal ninu, ko si tẹ ẹ si Aljannah onidẹra.

No comments:

Post a Comment