IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 3 May 2026

Igbimọ Agba Ọṣun ranṣẹ ibanikẹdun si Sooko Lawal


Igbimọ Agba ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọṣun ti ranṣẹ ibanikẹdun si alaga ẹgbẹ naa, Sooko Tajudeen Lawal lori iku iyawo rẹ, Fatimoh OreOluwa Lawal.


Alhaja Lawal lo jade laye lọjọ Kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun yii lẹyin aisan ranpẹ.


Ninu atẹjade kan ti akọwe Igbimọ Agba, Hon. Ọmọlaoye O. Akintọla, fi sita ni wọn ti ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bii obinrin oniwa rere to ṣatilẹyin fun ọkọ rẹ.


Wọn gbadura pe ki Ọlọrun fori jin oloogbe, ko si fun ọkọ, awọn ọmọ, atawọn ẹbi ni ọkan lati gba iṣẹlẹ naa.

No comments:

Post a Comment