Awọn adari, ti wọn tun jẹ igbimọ ma-jẹ-o-bajẹ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ni ẹkun idibo Iwọ-Oorun Ọṣun ti ṣatẹnumọ ipinnu wọn pe Dokita Akin Ogunbiyi lawọn fa kalẹ lati dije dupoo ọmọ ile igbimọ aṣofin agba lati agbegbe wọn.
Ṣaaju nibi ipade kan ti wọn ṣe lọjọ Tọsidee, ọgbọnjọ oṣu kẹrin, ọdun yii nilee Ọjọgbọn Ladipọ niluu Iwo ni wọn ti kede ipinnu wọn ọhun.
Wọn ṣalaye nigba naa pe awọn mẹwaa ni wọn jade lati du tikẹẹti naa, awọn mẹwẹẹwa ọhun si ni Ogunbiyi, Bade Falade, Dọtun Babayẹmi, Basiru Adewinmbi, Peter Ogundeji, Mojeed Oluogun, Amere Gafar, Adegbenge Suraju Salawu, Adebayọ Waliyu Ọladosu ati Jẹnẹra Adeniran.
Awọn adari ọhun ni, lẹyin ifikunlukun to peye, awọn fọwọ si orukọ Ogunbiyi lati ẹkun idibo Iwo gẹgẹ bii oludije funpo sẹnetọ lati Iwọ-Oorun Ọṣun ninu idibo apapọ ọdun 2027.
Amọ saa deedee ni lẹta kan tun n lọ kaakiri pe awọn adari ti pohunda lori igbesẹ wọn, idi niyẹn ti alaga awọn adari ọhun, Hon. Ọmọlaoye O. Akintọla, fi sọ pe irọ to jinna sootọ ni ahesọ naa.
Ọmọlaoye ṣalaye pe awọn ko yi ipinnu awọn pada o, Dokita Ogunbiyi ni oludije tawọn fa kalẹ.
O gba awọn ọmọ ẹgbẹ APC lagbegbe naa niyanju lati yẹra fun ohunkohun to le da rugudu silẹ nibẹ.

No comments:
Post a Comment