Iroyin to n wa lati ilu Ẹsa Oke nipinlẹ Ọṣun ko fini lọkan balẹ rara.
Ohun ti a gbọ ni pe awọn oloye ilu naa ti kede konilegbele lọsan oni Wẹsidee.
Lati ọsẹ diẹ sẹyin ni ojojo ti n ṣe ogun kabiesi wọn, Ọba Adeyẹmi Akanbi Adediran, ti ara ogun ko le rara.
Ṣugbọn lọsan oni ni ahesọ bẹrẹ pe o ṣee ṣe ki kabiesi ti darapọ mọ awọn babanla rẹ.
Ọrọ yii tun gba ibomiran yọ nigba ti Ogboni ilu naa, Oloye Paul Ọlamiju kede konilegbele.
O ni ki wọn ti gbogbo ọja ilu naa pa, bẹẹ ni ko gbọdọ si ipẹjọpọ ayẹyẹ kankan lati irọlẹ oni titi di irọlẹ ọla.

No comments:
Post a Comment