Iṣẹlẹ buburu ọhun la gbọ pe o ṣẹlẹ niluu Oogi loju ọna Ọdeomu si Oṣogbo nirọlẹ ọjọ ọdun Ileya gan an.
Ori ọkada ni awọn ọlọpaa mejeeji ọhun; Tobi Ọdẹdina ati Kehinde Adeleke, wa, ti wọn si n lọ si ilu Orilẹ-Owu nigba ti ọkunrin kan to wa mọto Lexus kọlu wọn.
Loju ẹsẹ la gbọ pe Kehinde to joko lẹyin ọkada ku, nigba ti Tobi to wa ọkada naa jade laye ki wọn to gbe e deleewosan.
Nigba tawọn araalu fi maa debẹ, dẹrẹba mọto ọhun ti sa lọ, to si fi mọto silẹ sibẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l'Ọṣun, Abiọdun Ọjẹlabi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni mọto Lexus naa ti wa lagọ awọn, nigba ti iwadii ti bẹrẹ lati mu onimọto ọhun nibikibi to ba sa pamọ si.
Ọjẹlabi sọ siwaju pe wọn ti sinku ọkan lara awọn ọlọpaa meji yii nilana ẹsin Musulumi.
Ọmọbibi ilu Orilẹ-Owu ni wọn pe Tobi Ọdedina ni tiẹ.

No comments:
Post a Comment