Igun ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun, Association of Concerned Local Government Workers, ti ke si awọn alaga ijọba ibilẹ lati tubọ mu ọrọ igbayegbadun awọn oṣiṣẹ lọkunkundun.
Bakan naa ni ẹgbẹ ọhun ke si awọn ọmọ ẹgbẹ lati ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ati oludije rẹ, Alhaji Bọla Oyebamiji ninu idibo gomina to n bọ loṣu Kẹjọ ọdun yii.
Nibi ayẹyẹ ti wọn ṣe fun ayajọ ọjọ awọn oṣiṣẹ to waye ninu ọgba ijọba ibilẹ Ọlọrunda niluu Oṣogbo ni adari wọn, Comrade Adedayọ Adekunle, ti sọrọ yii.
Gbogbo ẹka lawọn oṣiṣẹ naa ti ni aṣoju pẹlu aṣọ ẹgbẹjọda ti wọn wọ, fọọfọ si ni ibi ti wọn ti ṣe ayẹyẹ naa kun bẹrẹ lati aago mẹwaa owurọ.
Ninu ọrọ apilẹkọ rẹ, Adekunle sọ pe ki i ṣe ohun to boju mu ki wọn maa sọ pe awọn kan wa ti wọn n ṣiṣẹ nileeṣẹ ijọba gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ latari pe ijọba ko tii gba wọn wọle, iyẹn casual workers, o rọ ijọba lati tete wa nnkan ṣe si iru ọrọ bẹẹ.
Adekunle beere fun aabo to peye fun awọn oṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun, ki wọn le maa fọkan balẹ ṣiṣẹ wọn bo ṣe yẹ.
Bakan naa lo ke sijọba lati tete maa yanju ohunkohun to ba jẹ ipenija awọn oṣiṣẹ ki iru rẹ to yọri si iyanṣẹlodi.
O ni lẹyin ọpọlọpọ iwadii nipa oludije funpo gomina Ọṣun latinu ẹgbẹ APC, Bọla Oyebamiji, awọn oṣiṣẹ ri i bii ẹni to ṣe e fọkan tan, nitori naa lawọn ṣe pinnu lati ṣatilẹyin fun un.
Nigba to n ba awọn oṣiṣẹ sọrọ, alaga fun gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ igun ti ẹgbẹ APC l'Ọṣun, Hon. Samuel Idowu, fi da awọn oṣiṣẹ loju pe igba ọtun ni wọn wa yii, owo oṣu wọn yoo maa lọ deede, gbogbo ajẹmọnu wọn ko nii duro, bẹẹ ni idanilẹkọọ loorekoore yoo maa wa fun wọn lati le jafafa sii lẹnu iṣẹ wọn.

No comments:
Post a Comment