Alakoso Agba fun igbimọ ipolongo ibo saa keji fun Gomina Ademọla Adeleke, Sẹnetọ Lere Oyewumi, ti fi ọwọ mejeeji sọya pe, lai si rogbodiyan rara, Adeleke yoo jawe olubori ninu idibo ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.
Oyewumi, ẹni to jẹ aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Iwọ-Oorun Ọṣun nile igbimọ aṣofin agba, sọ niluu Oṣogbo lọjọ Sannde to kọja pe bi awọn ko ba lẹ posita ipolongo ibo fun Ademọla Adeleke, gbogbo awọn eeyan Ọṣun ni wọn ti ṣetan lati fi ibo wọn ṣatilẹyin fun un.
O ni awọn ko dakẹ lori wahala ti awọn ẹgbẹ alatako n gbe dide si awọn ọmọ ẹgbẹ Accord lojoojumọ, to fi mọ bi wọn ṣe n ba patako ipolongo ibo ati posita aworan Gomina Adeleke jẹ, o si daju pe awọn ẹṣọ alaabo yoo gbe igbesẹ to nitumọ lori rẹ laipẹ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, "Ohun to jẹ ka maa ke ni pe awa la wa nijọba, wọn si ni ẹni to ni ori ni ori maa n fọ. Igba taa wa ni ẹgbẹ alatako, bi wọn ṣe gbogun ti wa naa niyii.
"Ti a ba lẹ posita lọsan, ko le di ọjọ keji, ti a ba ṣe patako ipolongo ibo laarọ, wọn a ti ja a lulẹ ko to di irọlẹ, nigba ti wọn wa nijọba. A tun waa wa nijọba, a ṣe patako ipolongo ibo, wọn tun ya a, arifin ni.
"Ṣugbọn nitori pe ẹni ti wọn maa sọ lẹnu ni wọn n wa. Bi Gomina Ademọla Adeleke ko ba ṣe posita l'Ọṣun, oju rẹ pawo. Awọn ara Ọṣun ti tọ gbogbo kini yii wo, wọn ti ri onikaluku tan, wọn ti ri igba ti onikaluku gbe, igba oyin ni Ademọla gbe. Ẹ fọkan yin balẹ, lagbara Ọlọrun, ẹni to jẹ ọga ọlọpaa lorileede Naijiria bayii, IG Disu, ti ẹ ba wo ọwọ to mu, ọwọ alaafia ni, o bẹrẹ daadaa, Ọlọrun a si jẹ ko gunlẹ daadaa.
"O fi ọkan wa balẹ pe ko nii si wahala nigba ibo nitori awa naa ko nii dakẹ ko to digba yẹn. Gbogbo wa la gbọdọ pawọ pọ lati sọ ẹni to ba n ṣe aidaa, ẹ foju fo ẹgbẹ to ba wa, e fi oju ẹni to huwa naa han faraye. Gbogbo nnkan to ba le da omi alaafia Ọṣun ru, ẹ ko nii ba awa nibẹ nitori ẹgbẹ PDP ti a ti wa ki i ṣe ẹgbẹ onijagidijagan. A ti ko gbogbo rẹ ti Ọlọrun bayii, a si mọ pe yoo gbakoso."



No comments:
Post a Comment