Akọwe apapọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla, ti fi da awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun loju pe wọn ko nii kabamọ ti wọn ba dibo fun oludije funpo gomina ninu ẹgbẹ naa, Dokita Najeem Salaam.
Nibi ipade apapọ kan ti wọn ṣe niluu Ileṣa lọjọ Sannde to kọja ni Arẹgbẹṣọla ti sọ pe ẹni ti gbogbo aye fẹran, to jẹ olotitọ, to si ni afojusun rere ni Salaam.
Gomina ijẹta nipinlẹ Ọṣun ọhun sọ siwaju pe Salaam yoo bẹrẹ oniruuru iṣẹ idagbasoke kaakiri ipinlẹ Ọṣun latibi ti iṣejọba oun gbe e de lọdun 2018, o si daju pe ko nii ja awọn araalu ni tan-an-mọ.
O ni awọn ti wọn n ṣejọba apapọ lorileede yii lọwọlọwọ ti kuna ninu ojuse ipese ọrọ-aje to duroore ati eto aabo to peye, idi niyẹn ti awọn fi ta kete si wọn.
Arẹgbẹṣọla ni lai fi ti atako ati ipenija to n koju ẹgbẹ ADC latọwọ awọn ti wọn fẹẹ pa wọn lẹnu mọ ṣe, ojoojumọ ni ẹgbẹ naa n tẹ siwaju.
O wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati maṣe kaarẹ tabi ṣojo nitori didun lọsan yoo so.

No comments:
Post a Comment