Oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Alhaji Bọla Oyebamiji, ti fun akẹkọọ to pegede julọ ni Ladoke Akintọla University of Technology to wa niluu Ogbomọṣọ nipinlẹ Ọyọ ni ẹbun miliọnu kan naira.
Akẹkọọ ọhun, Ọladepo Caleb Olugbenga, lo jẹ ọmọbibi ilu Ijimọba ninu ijọba ibilẹ Ejigbo nipinlẹ Ọṣun, oun lo si gba maaki to pọ ju lasiko ayẹyẹ ikẹkọọjade ẹlẹẹkejidinlogun iru ẹ ni fasiti naa.
Maaki 4.89 ni Caleb ni ninu maaki 5.0, eyi to si jẹ iwuri nla fun gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Ọṣun ti wọn wa nibi ayẹyẹ naa.
Nigba to n fun un ni ẹbun owo ọhun niluu Oṣogbo, Oyebamiji sọ pe ojuṣe ijọba ni lati maa ṣe koriya fun akẹkọọ to ba ṣe daadaa ninu ẹkọ rẹ.
O ni inu oun dun pupọ pẹlu bi akẹkọọ naa ṣe fakọyọ laaarin awọn akẹẹgbẹ rẹ. O ni bo tun ṣe bọ sori ikanni ayelujara lati kede faraye pe eto iranwọ awọn akẹkọọ, NELFUND, ti Aarẹ Tinubu gbe kalẹ lo ran oun lọwọ fun aṣeyọri naa jẹ nnkan iwuri.
Oyebamiji ṣalaye pe oun ti Caleb ṣe yii fi han pe awọn ọdọ ọmọ orileede Naijiria ni agbara ati ipa lati bori ohunkohun to ba jẹ ipenija wọn ti wọn ba lanfaani si iranwọ.
O ni ọkẹ aimọye ipenija adanipada-sẹyin ni Caleb doju kọ ninu irinajo rẹ ni Fasiti ọhun, ṣugbọn ko faaye gba wọn lati bu omi tutu si i lọkan, o si fakọyọ.
Oyebamiji gboriyin funjọba apapọ lori owoyaa NELFUND ti ọpọlọpọ akẹkọọ n rọgbọku le lori bayii, o ni ipa rere ni eto naa n ni lori awọn akẹkọọ lọwọlọwọ.
Bakan naa lo ṣeleri fun awọn ọdọ nipinlẹ Ọṣun pe ni kete ti wọn ba ti fi ibo wọn gbe oun wọle lọjọ Kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, oniruuru eto iranwọ ni yoo wa fun wọn, paapaa, eyi to nii ṣe pẹlu eto-ẹkọ wọn.
Caleb ati Iya rẹ dupẹ lọwọ Oyebamiji fun ẹbun nla naa. Wọn ni o bọ si asiko to dara ninu idile wọn.

No comments:
Post a Comment