IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 3 June 2026

O doju ẹ! Wọn ti ji aburo Adelabu Pẹnkẹlẹmẹsi gbe n'Ibadan o


Nnkan bii aago meje aabọ aarọ oni Wẹsidee, ọjọ Kẹta, oṣu kẹfa la gbọ pe awọn agbebọn da mọto Arabinrin Busayọ Adegoke duro lagbegbe Challenge niluu Ibadan.


Wọn gbe oun atawọn ibeji ọmọ rẹ; Peter ati Paul, ti wọn jọ wa ninu mọto alawọ pupa ọhun gbe.


Busayọ, ẹni ọdun mẹtalelogoji, ni wọn pe ni aburo minisita fun ọrọ ina ọba lorileede yii tẹlẹ ati ọkan lara awọn to kopa ninu idibo abẹle ẹgbẹ APC funpo gomina ipinlẹ Ọyọ, Adebayọ Adelabu.


Titu digba ti a n koroyin yii jọ, ko sẹni kankan to tii gburo ibi ti awọn mẹtẹẹta wa, bẹẹ ni awọn agbebọn naa ko tii ba awọn mọlẹbi rẹ sọrọ.


Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Kẹẹdogun oṣu Karun ọdun yii lawọn agbebọn ji akẹkọọ mọkandinlogoji ati olukọ meje nipinlẹ Ọyọ yii kan naa.

No comments:

Post a Comment