IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 30 June 2026

Alaga ijọba ibilẹ Guusu Ẹdẹ dẹrin pẹẹkẹ ẹgbẹrun kan eeyan, o rọ wọn lati gbaruku ti Adeleke


O kere tan, ẹgbẹrun kan eeyan ni wọn janfaani eto iranwọ ti wọn pe ni Imọlẹ Empowerment Programme labẹ alaga ijọba ibilẹ Guusu Ẹdẹ nipinlẹ Ọṣun, Hon. Lukman Afọlabi.


Lara awọn to janfaani eto ọhun to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee niluu Ẹdẹ, la ti ri awọn obinrin, awọn ọdọ, awọn oniṣẹ-ọwọ atawọn to ku diẹ kaato fun lagbegbe naa.


Afọlabi, ẹni ti awọn eeyan mọ si Abere Soose, ṣalaye nipa afojusun eto naa. O ni o wa lati sin inira eto ọrọ-aje to dẹnukọlẹ lorileede yii bayii ku laarin ilu ati lati jẹ kawọn eeyan le da duro lai rọgbọku le ẹnikẹni.


O ni eto naa ko ṣẹyin akitiyan Gomina Ademọla Adeleke lati maye rọrun fun awọn araalu, eleyii ti iṣejọba rẹ si n ṣe latigba to ti dori aleefa.



Afọlabi lo asiko naa lati ke si Aarẹ Bọla Tinubu lati da si yiyọnda owo awọn ijọba ibilẹ l'Ọṣun lati le lanfaani sisan owo awọn ọba, awọn olukọ ileewe alakọbẹrẹ, awọn oṣiṣẹ eto ilera atawọn oṣiṣẹfẹyinti.


O rọ awọn to janfaani eto naa lati lo o daadaa, ki idagbasoke si ba awujọ nipasẹ wọn. Bakan naa lo rọ wọn lati faaye gba aalafia; ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo gomina lọjọ Kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ki wọn si gbaruku ti Adeleke fun itẹsiwaju oniruuru iṣẹ idagbasoke l'Ọṣun.


Ninu ọrọ tirẹ, Kọmiṣanna fun ọrọ ẹgbẹ alajẹsẹku ati ilonilagbara, Adebayọ Ogungbangbe, ṣalaye pe kaakiri awọn ijọba ibilẹ ọgbọn to wa l'Ọṣun ni wọn ti n ṣe iru eto ọhun.


O ni Gomina Ademọla Adeleke ni imọlara ohun ti awọn araalu n doju kọ lasiko ti a wa yii, idi niyẹn to fi pinnu lati ran wọn lọwọ fun imugbooro okoowo wọn.


Ogungbangbe parọwa si awọn araalu lati maṣe faaye gba iwa jagidijagan, o ni ibo wọn ni ki wọn fi sọrọ, ki wọn si maa ranti pe eeyan alaafia ni Gomina Adeleke.


O ni ki wọn dibo fun itẹsiwaju oniruuru iṣẹ idagbasoke ti Adeleke ti dawọle.



Lara awọn to janfaani eto naa ni Comrade Adeyẹmi Alapa ati Ọlawusi Rebecca. Awọn mejeeji gboṣuba fun Gomina Adeleke ati Hon. Afọlabi fun afojusun daradara naa.


Alapa, ẹni to jẹ alaga fun igbimọ ipolongo atundi ibo gomina fun awọn akanda, sọ pe iṣejọba yii lo farajin ju lati dẹrin pẹẹkẹ awọn akanda ẹda. O si ṣeleri pe o di dandan ki gomina tẹ ilẹ tutu loṣu kẹjọ nitori o ti da'mi siwaju.

No comments:

Post a Comment