Akọwe apapọ tẹlẹ fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lorileede yii, Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore, ti sọ pe digbi loun wa ninu ẹgbẹ naa ati pe oun ko figba kankan sọ fun ẹnikẹni lati darapọ mọ ẹgbẹ Accord.
Nibi ipade oloṣooṣu Igbimọ Agba ẹgbẹ APC Ọṣun to waye niluu Ilobu nijọba ibilẹ Irẹpọdun lọjọ Tusidee ni Omiṣore, ẹni ti oun naa fi erongba han lati gba tikẹẹti ẹgbẹ naa fundije gomina ko too di pe o ja mọ Aṣiwaju Bọla Oyebamiji lọwọ, ti sọ pe gbogbo afojusun oun bayii ni bi ẹgbẹ naa yoo ṣe jawe olubori loṣu Kẹjọ ọdun yii.
Omiṣore, ẹni to sọrọ nipasẹ alakoso eto ipolongo ibo rẹ, Ajibọla Famurewa, sọ pe ko sẹni to le jade sita lara awọn to ti kọwe fi ẹgbẹ APC silẹ l'Ọṣun bayii pe oun loun sọ fun wọn lati ṣe bẹẹ, oun ko si figba kankan ba ẹnikẹni sọ ọ pe oun ti fi ẹgbẹ silẹ.
O ni onikaluku wọn le ni nnkan to n bi wọn ninu, oun si ṣa ipa oun lati ba wọn sọrọ, ṣugbọn wọn ko gbọ, amọ, ojulowo ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC loun, ajumọṣe si ni aṣeyọri Oyebamiji.
Ṣaaju ni alaga igbimọ agba, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, ti ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lati fimọ ṣọkan fun ijawe olubori ninu ibo gomina ọhun.
O ni ẹgbẹ naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ to pọ, ti wọn ba si ṣiṣẹ papọ, yoo rọrun fun wọn lati rọwọ mu ninu idibo naa.

No comments:
Post a Comment