Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ni iha Iwọ-Oorun Ọṣun ti ṣeleri lati ṣiṣẹ papọ fun aṣeyọri ẹgbẹ naa ninu idibo gomina oṣu Kẹjọ ati idibo apapọ ọdun to n bọ.
Lẹyin ipade kan ti awọn eekan ẹgbẹ naa ṣe nile ẹgbẹ wọn to wa niluu Iwo lọjọ Kejila, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni wọn ti sọ pe aṣeyọri idibo gomina to n bọ ọhun pọn dandan fun ominira awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun.
Gẹgẹ bi alaga wọn lẹkun idibo ọhun, Hon. Akintọla Ọmọlaoye, ṣe fi sita, gbogbo ọmọ ẹgbẹ ni wọn ti sọ pe awọn yoo ṣa ipa wọn fun ijawe olubori oludije ti wọn gbe kalẹ funbo gomina.
Awọn adari tun rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati gbe igbimọ ipolongo kalẹ kaakiri agbegbe to wa labẹ ẹkun idibo ijọba apapọ naa lati le mu ki iṣẹ naa rọrun fun wọn.
Wọn gbadura fun atilẹyin Ọlọrun ninu idibo gomina ipinlẹ Ọṣun ati idibo apapọ ọdun 2027.

No comments:
Post a Comment