Wọn ti kede iku agba oṣere tiata ilẹ wa nni, Alagba Kọla Oyewọ.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 1946 ni wọn bi baba yii.
Ọkan lara awọn oṣere tiata, Kunle Afod lo tufọ iku baba naa, ẹni to ni o dagbere faye lalẹ oni, ọjọ kejila oṣu kẹfa, ọdun 2026.
Ọmọbibi ilu Ọba-Ile nipinlẹ Ọṣun ni, inu ẹgbẹ oṣere tiata Baba Oyin Adejọbi lo si ti kọkọ bẹrẹ ere itage.
O kopa ninu fiimu nla bii Ṣaworo Idẹ, Agogo Eewọ, Koṣeegbe ati bẹẹ bẹẹ lọ

No comments:
Post a Comment