IROYIN YAJOYAJO

Monday, 8 June 2026

Irọ ni o! Mi o gbe ẹgbẹ oṣelu APC lọ si kootu o - Ajagunla


Sẹnetọ to n sọju awọn eeyan Aaringbungbun Ọṣun nile igbimọ aṣofin agba lorileede yii, Sẹnetọ Fadeyi Ajagunla, ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ kan to n lọ kaakiri pe oun gbe ẹgbẹ oṣelu APC lọ si kootu.

O ni lootọ loun ti gbe abajade idibo abẹle ẹgbẹ naa to waye loṣu to kọja lọ siwaju igbimọ ti ẹgbẹ gbe kalẹ lati gbọ awuyewuye to ba ṣẹlẹ ninu idibo naa, ṣugbọn ki i ṣe kootu.

Nigba to n sọrọ lori foonu lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, o ni irọ ni ahesọ naa, ko si nnkan to jọ bẹẹ.

Laipẹ ni iroyin kan jade pe Ajagunla ti gbe ẹgbẹ APC ati ẹni ti wọn kede pe o jawe olubori ninu idibo abẹle naa, Rasheed Adegoke, lọ si kootu.

Tẹ o ba gbagbe, ninu idibo abẹle ẹgbẹ APC to waye lati fi mu ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu idibo apapọ ọdun to n bọ, nibẹ ni wọn si ti mu Adegoke, ti Ajagunla si sọ pe ko sibi kankan tidibo ti waye lagbegbe naa, ati pe inu otẹẹli ni wọn ti kọ esi idibo.

No comments:

Post a Comment