IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 30 June 2026

Gbogbo amuyẹ lati gbajọba lọwọ Gomina Ademọla Adeleke ni mo ni - Adeṣina Adeyẹmi


Oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Grand Alliance, APGA, Ọmọọba Adeṣina Adeyẹmi-Doro, ti sọ pe idi ti oun fi pinnu lati gbajọba lọwọ Adeleke ni lati gbe ijọba to ni akoyawọ, to si ni imọlara ilakọja awọn araalu kalẹ.



O ni ọpọlọpọ nnkan alumọni ni Eledua fi jinki ipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn o nilo adari to ni afojusun rere, to si mọ nnkan to n ṣe lati le ṣawari awọn nnkan naa.


Nigba to n ba Gbagede sọrọ, o ni gbogbo awọn iṣejọba to ti kọja l'Ọṣun ati eyi to wa nibẹ lọwọlọwọ ni wọn ti gbiyanju, ṣugbọn ipinlẹ yii nilo adari tuntun, to jafafa, to si mọ nnkan to tọ sawọn araalu.


O ni 'Erongba mi ki i ṣe ti ifẹ ara ẹni tabi orogun oṣelu, bi ko ṣe lati ṣatunto ipinlẹ yii lọna ti yoo mu idagbasoke ati itẹsiwaju ti ko lẹgbẹ wa. Idibo yii gbọdọ mu ayipada rere ba ipinlẹ wa, ki i ṣe ọrọ itara lori oludije.


'Awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun nilo adari ti yoo mu nnkan rọrun fun wọn, ti yoo si pese iṣejọba to duroore ni gbogbo ẹka iṣejọba.''


Adeyẹmi-Doro sọ siwaju pe awọn ọdọ nilo iṣẹ to nitumọ, awọn oniṣẹ-ọwọ nilo iranwọ ati idanilẹkọọ ti yoo fun wọn ni imọ kikun lori eto ọrọ-aje igbalode.


O ni ti awọn agbẹ ba ri iranlọwọ latọdọ ijọba lati ra awọn irinṣẹ igbalode, ti wọn si lanfaani si owo lati fi da'ko, ounjẹ lọpọ yantuuru yoo wa nipinlẹ Ọṣun.


O fi kun ọrọ rẹ pe iṣejọba oun yoo mojuto eto-ẹkọ, ilera pipe, igbayegbadun awọn olukọ, atunṣe awọn ileewe, atunṣe ọja kaakiri, ati bẹẹ bẹẹ lọ.


O rọ awọn araalu lati ṣatilẹyin fun oun, ki wọn fi ibo wọn gbe oun wọle ninu idibo ọjọ Kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ki ipinlẹ Ọṣun le goke agba.

No comments:

Post a Comment