IROYIN YAJOYAJO

Monday, 29 June 2026

Igbimọ Agba Ọṣun ba Ajibọla Baṣiru kẹdun iku iya rẹ


Igbimọ Agba ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọṣun ti ranṣẹ ibanikẹdun si akọwe apapọ ẹgbẹ naa lorileede yii, Dokita Ajibọla Baṣiru, lori iku iya rẹ, Alhaja Sidikat Abẹkẹ Baṣiru.


Alhaja Baṣiru ni wọn kede ipapoda rẹ lọjọ Aiku, Sannde to kọja.


Ninu atẹjade kan ti alaga igbimọ Agba, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, fọwọ si ni wọn ti sọ pe ibanujẹ nla ni lati padanu iru abiamọ tootọ bẹẹ.


Ẹnjinia Akinwumi sọ pe ṣe ni awọn mọlébi gbọdọ gba itunu pe Allah lo n fun ni, to si tun n gba a lasiko to ba wu u.


O gbadura pe ki Allah tu Ajibọla Baṣiru atawọn mọlẹbi Alhaja Baṣiru ninu lasiko ipenija nla yii, ki Allah si fi Aljanal Fidaus ta mama naa lọrẹ.

No comments:

Post a Comment