Alakoso Agba fun igbimọ ipolongo ibo ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọṣun, Hon. Oluwọle Ọkẹ, ti sọ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iku ọkunrin tawọn oloṣelu pa niluu Ẹsa-Oke laipẹ yii, Rọgba Ajayi, ko nii nisinmi.
Ninu atẹjade kan to fi sori feesibuuku rẹ ni Ọkẹ ti sọ pe ko da oun loju pe oun ṣalabapade Rọgba ri nigba aye rẹ, o si ya oun lẹnu pe ṣe ni Gomina Ademọla Adeleke n rọjo epe le oun lori nitori iku baba ọlọmọ mẹrin ọhun.
Gẹgẹ bo ṣe wi, bi Adeleke ṣe n ṣepe fun oun, to si n bu oun lasiko to ṣabẹwo ibanikẹdun siluu Ẹsa-Oke laipẹ yii ṣafihan iru ẹkọ-ile to ni, ati ẹkọ to n fun awọn ọmọ rẹ.
O ni ọrọ ti ko kan oun lọwọlẹsẹ ni wọn n darukọ oun si, amọ ohun kan to daju ni pe Gomina Adeleke yoo lulẹ lasiko ibo ọjọ Kẹẹẹdogun oṣu kẹjọ ọdun yii nitori oogun oju oun ni iṣejọba ti idile naa n gbadun bayii.
Ọkẹ sọ siwaju pe oun yọnda Adeleke pẹlu oniruuru ọrọ ibajẹ to sọ si oun latari pe o wa labẹ aabo ofin gẹgẹ bii gomina lọwọlọwọ, ṣugbọn awọn yoo jọ mu nnkan nilẹ ni kootu lẹyin to ba kuro lọfiisi lọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun yii.

No comments:
Post a Comment