IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 27 June 2026

Ṣe ni Gomina Adeleke fi ẹsin lu wa ni jibiti lọdun 2022, ko saaye fun iru rẹ mọ l'Ọṣun - Awọn Musulumi


Agbarijọ awọn lamẹẹtọ ninu ẹsin Islam ati awọn Alfa, Concerned Muslim Stakeholders and League of Alfas, nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe awọn ko nii faaye gba ohun to ṣẹlẹ ti awọn fi dibo fun Gomina Ademọla Adeleke lọdun 2022 ko tun ṣẹlẹ ninu idibo to n bọ yii.


Wọn ni ṣe ni Adeleke fi 'Nurudeen' to wa ninu orukọ rẹ lu awọn ni jibiti, eyi to si jẹ ki awọn ro pe musulumi ododo ni ti awọn fi dibo fun un.


Nibi ipade oniroyin ti wọn ṣe niluu Oṣogbo ni aarẹ wọn, Sheikh Qozeem AbdulRahaman to jẹ Mudhirul Morqas Assaqofy niluu Iwo, ti sọ pe lẹyin ti awọn joko, ti awọn si gbe awọn oludije funpo gomina wo daadaa, awọn pinnu lati ṣatilẹyin fun Aṣiwaju Munirudeen Oyebamiji labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.


O wa ke si awọn musulumi kaakiri Ọṣun lati tu yaaya dibo wọn fun Oyebamiji lọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun yii.


Bakan naa ni akọwe wọn, Mallam Abdulganiy Ọlaide Ezra, sọ pe Mọnafiki Adini ni oun ti Adeleke ṣe fun awọn lọdun 2022, eyi to si yọri si bi Kristiani meji ṣe wa nigbọnnu iṣakoso ipinlẹ Ọṣun nitori o ti han gbangba pe Kristiẹni ni gomina ati igbakeji rẹ.


O ni ko ṣee ṣe fun awọn lati laju silẹ lẹẹkeji ki iru eyi tun waye, iyanjẹ nla ni yoo jẹ fun awọn. O ni lati ọdun mẹrin iṣejọba Adeleke, ko sigba kankan to mu ọrọ awọn Musulumi lọkunkundun rara, bẹẹ ni awọn mọlẹbi rẹ ko ṣe nnkan kan lati maye rọrun fawọn.


Mallam Ezra fi kun ọrọ rẹ pe ko sẹnikankan ti ko mọ Oyebamiji gẹgẹ bii musulumi ododo, bẹrẹ lati ilu rẹ, titi kaakiri ipinlẹ Ọṣun, idi si niyẹn tawọn fi pinnu lati gbaruku ti i fun itẹsiwaju ati imugbooro ẹsin Islam.

No comments:

Post a Comment