Titi di bi a ṣe n kọroyin yii, ileewosan UNIOSUNTH ni alaga ẹgbẹ Accord funjọba ibilẹ Oṣogbo, Hon. Asimiyu Ajibọla, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Isila, wa nibi to ti n gbatọju lẹyin tawọn agbebọn kan ṣekọlu si i.
Nnkan bii aago mẹwaa alẹ ku iṣẹju mẹwaa lọjọ Wẹsidee, ọjọ Kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun yii la gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lagbegbe MDS niluu Oṣogbo.
A gbọ pe alaga yii pẹlu awọn ọrẹ rẹ ni wọn jọ wa ninu mọto Toyota Corolla alawọ omi-aro, lojiji ni wọn bẹrẹ si i gburo ibọn, ti awọn agbebọn naa si doju ibọn kọ ọgangan abala ibi ti alaga naa joko si.
Ọkan lara awọn to wa pẹlu Ajibọla ṣalaye pe ẹni to wa mọto awọn sa asala wọnuu agọ ọlọpaa to wa ni Dugbẹ ko too di pe awọn agbebọn naa pada lẹyin wọn.
O ni bi awọn ṣe fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa Dugbẹ leti tan lawọn mori le ileewosan UNIOSUN latari ifarapa ti alaga naa ni, nibẹ lo si wa titi dasiko yii.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ Ọṣun, Oluọmọ Kọlapọ Alimi, bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, o si ke si ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣewadi kikun ni kiakia lori rẹ.
Alimi sọ pe gbogbo awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa lawọn ọlọpaa gbọdọ ṣawari lẹyọkọọkan, ki wọn si fi iya to tọ jẹ wọn.

No comments:
Post a Comment