Gomina Ademọla Adeleke ti sọ fun gbogbo awọn ẹṣọ alaabo patapata lati fi pampẹ ofin gbe ẹnikẹni to ba n pe ara rẹ ni oloye ẹgbẹ awakọ NURTW kaakiri awọn ibudokọ nipinlẹ Ọṣun.
Lẹyin ipade awọn ọmọ igbimọ to n ri si eto aabo nipinlẹ Ọṣun to waye lọjọ Tọsidee ọsẹ yii ni Adeleke paṣẹ pe ko gbọdọ si gbigba owo garaaji mọ lọwọ awọn awakọ, bẹẹ ni ẹnikẹni ko gbọdọ pe ara rẹ ni oloye nibudokọ kankan mọ.
Aṣẹ yii ko ṣẹyin bi awọn igun ẹgbẹ awakọ to jẹ ti ẹgbẹ All Progressives Congress, labẹ alaga wọn tẹlẹ, Kazeem Oyewale, ṣe gba awọn garaaji ọkọ, ti awọn alaga kansu ẹgbẹ APC si kede Oyewale gẹgẹ bii alaga wọn bayii.
Adeleke, ninu ipade to ṣe pẹlu awọn ọlọpaa, ọtẹlẹmuyẹ, ileeṣẹ ologun, Sifu Difẹnsi, NDLEA, Ajọ alamojuto ọgba ẹwọn, ajọ to n ri si iwọlewọde awọn ajeji, ajọ ẹṣọ ojuupopo, NAPTIP, Amọtẹkun ati bẹẹ bẹẹ lọ, sọ pe alaafia gbọdọ pada si awọn ibudokọ kaakiri ipinlẹ Ọṣun.
Gẹgẹ bi Kọmiṣanna fun eto iroyin, Oluọmọ Kọlapọ Alimi, ṣe fi sita, gomina ni ki i ṣe pe ki wọn ti awọn garaaji pa o, ṣe ni ki wọn ri i daju pe ẹnikẹni ko pe ara rẹ ni oloye ẹgbẹ awakọ, ẹni to ba si tasẹ agẹrẹ si aṣẹ naa, ki wọn fi pampẹ ofin gbe e fun ẹsun dida omi alaafia ilu ru, ki iru ẹni bẹẹ si foju bale-ẹjọ.
Gomina fi kun ọrọ rẹ pe ki gbogbo awọn ẹṣọ alaabo naa gbe igbimọ amuṣẹya kalẹ kiakia fun ifẹsẹmulẹ aṣẹ naa.
Gbogbo awọn ẹṣọ alaabo to wa nibi ipade naa la gbọ pe wọn ṣeleri lati fọwọsowọpọ pẹlu gomina lori aṣẹ tuntun yii.

No comments:
Post a Comment