IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 18 July 2026

Ọdẹyẹmi kuro ninu ẹgbẹ NNPP, lawọn ọmọ ẹgbẹ ba fọnka l'Ọṣun


Alaga ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party nipinlẹ Ọṣun, Dokita Tosin Ọdẹyẹmi, ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ bayii.


Ọdẹyẹmi, ẹni to ti n tukọ ẹgbẹ naa lati nnkan bii ọdun mẹfa sẹyin, la gbọ pe o kọwe fi ẹgbẹ silẹ lọjọ Kẹrindinlogun, oṣu Keje, ti a wa yii latari wahala to n mi ẹgbẹ naa logbologbo lorileede Naijiria bayii.


Ṣugbọn bi Ọdẹyẹmi ṣe fi ẹgbẹ silẹ la gbọ pe ọja tu fun ẹgbẹ naa, ṣe lawọn oloye atawọn ọmọ ẹgbẹ n fiwe silẹ, ti wọn lawọn o ṣe mọ.


Igbakeji adari awọn obinrin lorileede yii, Hon. Ṣọlape Ọlatunbọsun  ati akọwe fun ẹkun Guusu Iwọ-Oorun, Hon. Ọlalekan Fabayọ, sọ pe awọn ko ṣe ẹgbẹ NNPP mọ lẹyin ti awọn ṣagbeyẹwo bi ọjọọwaju ẹgbẹ naa ṣe n lọ.


Bakan naa ni igbakeji akọwe ẹgbẹ l'Ọṣun, Adegbaju Celestinah, akọwe alamojuto, IfẹOluwa Akinfala, alaga ẹgbẹ ni ẹkun idibo Ifẹ/Ijeṣa, Prophet Peter O. Blessed ati igbakeji adari awọn obinrin nipinlẹ Ọṣun, Arabinrin Ọladoṣu, la gbọ pe awọn naa ti kọwe fi ẹgbẹ ọhun silẹ bayii.


A o maa fi ẹkunrẹrẹ nipa bo ṣe n lọ ninu ẹgbẹ naa to yin leti.

No comments:

Post a Comment