Ajọ kan to n ri si idagbasoke ijọba tiwantiwa nipinlẹ Ọṣun, iyẹn, Concerned Stakeholders for Democracy in Osun, ti ke gbajare pe ti awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ba sun asunpiye lasiko yii, afaimọ ki ẹgbẹ oṣelu APC ma gbe ru wọn latẹyin.
Ajọ naa ṣalaye pe gbogbo eto ni ẹgbẹ APC ti pari nibi ipade kan ti wọn ṣe laipẹ yii pẹlu Oloye Nyesom Wike, Alhaji Adegboyega Oyetọla, Oloye Bisi Akande, Alhaji Bọla Oyebamiji, IGP Tunji Diiṣu, aṣoju alaga ajọ eleto idibo ilẹ wa ati bẹẹ bẹẹ lọ, lati ṣe magomago idibo ọjọ Kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, 'Iroyin to tẹ wa lọwọ fidi rẹ mulẹ pe lara awọn ọna ti wọn fẹẹ gba dabaru ipinnu awọn araalu lori idibo yii ni lilo mọto awọn ẹṣọ alaabo lati maa fi ko awọn tọọgi kaakiri.
'Wọn fẹẹ lo awọn mọto to ni ami idanimọ ileeṣẹ ọlọpaa lati fi ko awọn tọọgi kaakiri kọrọkọndu ipinlẹ Ọṣun. Iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ ni lati da wahala silẹ ati lati fi dunkoko mọ awọn oludibo, paapaa, lawọn agbegbe ti wọn mọ pe awọn ko ti le rọwọ mu.
'Ọna keji ti wọn tun fẹẹ gba ni fifi pampẹ ofin gbe awọn eeyan pẹlu ayederu ẹri. Wọn fẹẹ kun ọpọlọpọ ọkọ ni ami idanimọ ẹgbẹ Accord, awọn tọọgi agbebọn ti wọn a ko sinu rẹ maa daṣọ boju, wọn a ya fọto wọn. Fọto yii ni wọn a maa fi han awọn araalu lọjọ idibo pe awọn ti mu awọn ọmọ ẹgbẹ Accord, awọn si ti ti wọn mọle.
'Ṣaaju ọjọ idibo yii, wọn ti fun ileeṣẹ ọlọpaa ni aṣẹ lati mu awọn eeyan bii Aṣiri Ẹniba, Ojuyọbọ atawọn to n tẹle wọn. Wọn a waa tu wọn silẹ nigba ti idibo ba ku ọjọ meji lati ṣiṣẹ laabi ti wọn ran wọn.
'Bakan naa ni wọn ti pari gbogbo eto pẹlu Kọmiṣaana ajọ INEC nipinlẹ Ọṣun lati lo orukọ awọn ti ẹgbẹ APC ba fi silẹ gẹgẹ bii alamojuto eto idibo kaakiri awọn ijọba ibilẹ. Awọn yẹn nikan ni wọn yoo gba wọle nibudo ti wọn ti maa ko ibo jọ.
'Afojusun wọn lori eleyii ni pe wọn a ko ọpọlọpọ ayederu esi idibo wa si ọfiisi ajọ INEC niluu Oṣogbo lati awọn ijọba ibilẹ. Ẹgbẹ oṣelu to ba fi ẹhonu wọn, wọn a sọ fun un pe ṣe ni ko fori le kootu.
'Ohun miran ti wọn tun fẹnu ko si ni lati ko ọpọlọpọ awọn janduuku oludibo wọle. Ọkẹ aimọye kaadi idibo ni ajọ INEC ti ko fun ẹgbẹ APC lati pin fun awọn ọmọ ẹgbẹ wọn nipinlẹ Kwara, Ondo, Ogun, Eko, Ekiti ati Edo.
'Wọn ti ba gomina ipinlẹ Edo sọrọ lati ko ipa to jọju ninu eto buburu ti wọn ni ọhun. Wọn ti yan gomina yii lati ba wọn ko awọn jagunjagun agbegbe Niger Delta wọle, wọn a gba otẹẹli fun wọn, bẹẹ lawọn kan yoo maa sun ninu ile awọn ọmọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun, bẹrẹ lati ipari osu keje ti wọn a maa wọluu.
'Bakan naa ni wọn fẹẹ maa ba awọn aṣaaju ẹgbẹ Accord lorukọ jẹ, ti wọn a si maa fi pampẹ ofin gbe wọn. Erongba wọn ni lati maṣe fun awọn aṣaaju yii lanfaani lati jade ninu ile wọn lọjọ idibo, bẹẹ ni wọn ko nii le dibo.
'Koda, wọn tun ni awọn yoo maa fi pampẹ ofin gbe awọn aṣaaju ẹgbẹ Accord nibudo idibo, ti wọn a si maa fi ẹsun agbelẹrọ kan wọn. Awọn ẹsun bii pe wọn ka ibọn ati ọta mọ wọn lọwọ, ti wọn a si maa ko awọn ẹsibiiti irọ siwaju wọn. Bẹẹ ni wọn a tun sọ pe wọn ka owo to pọ ti wọn fẹẹ fi ra ibo mọ wọn lọwọ.
'Wọn tun ti gbe awọn kan kalẹ lati maa gbe ayederu iwe idibo, iyẹn Ballot Papers, kaakiri, wọn a si maa sọ pe gomina lo bẹ awọn niṣẹ. Bakan naa ni wọn tun ti pari eto lati ba orukọ ẹgbọn gomina, Dokita Deji Adeleke, jẹ nipa fifi ẹsun buburu kan an, a gbọ pe Oloye Wike ti sọ pe oun loun maa ṣiṣẹ iyẹn.
'A fẹẹ fi da awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun loju pe gbogbo imọ ati ete buburu ti wọn ni yii laṣiri wọn maa tu.
'Ajọ wa ki i ṣe ti ẹgbẹ oṣelu kankan. Ṣugbọn ohun ti a fẹ ni pe ki gbogbo ẹgbẹ oṣelu lanfaani si ẹtọ wọn lai si ibẹru. A duro fun ododo, ipin-dọgbandọgba ati idibo ti ko ni eru tabi magomago ninu.
'A n ke si ajọ INEC lorileede yii lati daabo bo orukọ rere wọn, ki ileeṣẹ ọlọpaa ṣiṣẹ wọn bii akọṣẹmọṣẹ lai ṣe'gbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kankan. Ki awọn orileede agbaye, awọn oniroyin atawọn ajafẹtọ-ọmọniyan si tanna wadii bi nnkan ṣe n lọ l'Ọṣun.
'A n ke si awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati maa ṣọra, ki wọn fọkanbalẹ, ki wọn si pinnu pe ko si ẹni to le halẹ mọ awọn, ki wọn si jade dibo bi wọn ṣe fẹ.'

No comments:
Post a Comment