Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti fidi rẹ mulẹ pe eeyan mẹta lo gbẹmi mi lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye sti Eiye kọju ija sira wọn niluu Ileṣa.
Gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Abiọdun Ọjẹlabi, ṣe wi, ni nnkan aago mẹjọ alẹ ni wahala naa bẹ silẹ lagbegbe Imọ, awọn mẹta to si ba iṣẹlẹ naa lọ ni Idowu, Yinka ati Ẹja.
O ni kia ni kọmiṣanna ọlọpaa to n ṣakoso idibo, Samuel Erale Etaifo paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa lọ sibẹ, lara awọn nnkan ti wọn ba nibẹ ni ọta ibọn mẹrin ati awọn ẹrọ ibanisọrọ.
Ọjẹlabi sọ siwaju pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, ti wọn si kilọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ọwọ ba tẹ nidi wahala fifa ati kiko awọn nnkan ija ogun kaakiri yoo fimu kata ofin.

No comments:
Post a Comment